1. Hánà sì gbàdúrà pé:“Ọkàn mi yọ̀ sí Olúwa;Ìwọ agbára mi ni a sì gbé sókè sí Olúwa.Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀ta mi,nítorí ti èmi yọ̀ ni igbala rẹ̀
2. “Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa;kò sí ẹlòmíràn bí kò se ìwọ;kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa.
3. “Má ṣe halẹ̀;má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jádenítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa,láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà.
4. “Ọrun àwọn alágbára ti ṣẹ́,àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.
5. Àwọn tí ó yọ̀ fún òunjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe,àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní: tóbẹ́ẹ̀ ti àgàn fi bí méje.Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára.
6. “Olúwa pa ó sì sọ di ààyè;ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà-òkú, ó sì gbé dìde.
7. Olúwa sọ di talákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀;ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè.
8. Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá,ó gbé alágbe sókè láti orí òkítì eérú wá,láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé,láti mu wọn jogún ìtẹ́ ogo:“Nítorí pé ọ̀wọ̀n ayé ti Olúwa ni,ó sì ti gbé ayé ka orí wọn
9. Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́,àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí.
10. A ó fọ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;láti ọrun wá ni yóò sánààrá sí wọn; Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,yóò si gbé ìwo ẹni-àmì-òróró rẹ̀ sókè.”
11. Elikánà sì lọ sí Rámà sí ilé rẹ̀, Ọmọ náà sì ń ṣe ìráńṣẹ́ fún Olúwa níwájú Élì àlùfáà.
12. Àwọn ọmọ Élì sì jẹ́ ọmọ Bélíálì; wọn kò mọ Olúwa.
13. Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀.