Sáàmù 71:4-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,ní ọwọ́ aláìsòdodo àti ìkà ọkùnrin.

5. Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Ọlọ́run,ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mí láti ìgbà èwe

6. Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;Ìwọ mu mi jáde láti inú ìyá mi wáèmi ó máa yìn ọ títí láé

7. Mo di ẹni ìyanu fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.

8. Ìyìn Rẹ̀ kún ẹnu mi,o ń sọ ti ọlá Rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo.

9. Má ṣe ta mí nù ni ọjọ́ ogbó miMá ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́

10. Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ òdì sí miàwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀

11. Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;lépa Rẹ̀ kí ẹ sì munítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”

12. Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti rànmí lọ́wọ́.

13. Jẹ́ kí wọn kí ó dààmúkí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mikí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkùbò àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14. Ṣùgbọ́n ní tèmí, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sì i.

15. Ẹnu mí yóò sọ nípa ti òdodo Rẹ,ti ìgbàlà Rẹ ni gbogbo ọjọ́lóòtọ́, èmi kò mọ́ iye Rẹ̀.

16. Èmi ó wá láti wá kéde agbára Olúwa Ọlọ́run;èmi ó kéde òdodo Rẹ̀ nìkan.

17. Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ tí kọ́ mítítí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀.

Sáàmù 71