Orin Sólómónì 5:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi;mo ti kó òjíá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ.Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi;mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi.Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu,àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́

2. Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí.Gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ilẹ̀kùn.“Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi,àdàbà mi, aláìlábàwọ́n miOrí mi kún fún omi ìrì,irun mi kún fún òtútù òru.”

3. Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà miṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀?Mo ti wẹ ẹsẹ̀ miṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?

4. Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ilẹ̀kùninú mi sì yọ́ sí i

5. Èmi dìde láti sílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,òjíá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi,òjíá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń ṣànsí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn

6. Èmi sí ilẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀.Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i.Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn

7. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ ìlú rí mibí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká.Wọ́n nà mí, wọ́n ṣá mi lọ́gbẹ́;wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi.Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!

8. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù, mo bẹ̀ yínbí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi,kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un?Ẹ wí fún un pé àìṣàn ìfẹ́ ń ṣe mi.

9. Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọÌwọ arẹwà jùlọ láàárin àwọn obìnrin?Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tó kù lọtí ìwọ fi ń rọ̀ wá bẹ́ẹ̀?

10. Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́nó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ.

11. Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọìdì ìrun rẹ̀ rí bí i ìmọ̀ ọ̀pẹó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò

12. Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbàní ẹ̀bá odò tí ń ṣàn,tí a fi wàrà wẹ̀,tí ó jìn, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́

13. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràríti ó sun òórùn tùràrí dídùnÈtè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílìó ń kán òjíá olóòórùn dídùn

14. Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà,tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíkáAra rẹ̀ rí bí i eyín erin dídántí a fi Ṣáfírè ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.

Orin Sólómónì 5