Lúùkù 6:23-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. “Kí ẹ̀yin yọ̀ ní ọjọ́ náà, kí ẹ̀yin sì fò sókè fún ayọ̀, nítorí tí ẹ̀yin ti gba ìtùnú yín ná.

24. “Ègbé ni fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀nítorí ẹ ti gba ìtùnú yín.

25. Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ó yó,nítorí ebi yóò pa yín,Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń rẹ́rìn-ín nísinsin yìí,nítorí tí ẹ̀yin ó ṣọ̀fọ̀, ẹ̀yin ó sì sọkún.

26. Ègbé ni fún yín, nígbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní rere,nítorí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn èké wòlíì.

27. “Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi: Ẹ fẹ́ àwọn ọ̀ta yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín;

28. Súre fún àwọn tí ń fi yín ré, sì gbàdúrà fún àwọn tí ń kẹ́gàn yín.

29. Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, pa èkejì dà sí i pẹ̀lú; àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù rẹ pẹ̀lú.

30. Sì fifún gbogbo ẹni tí ó tọrọ lọ́dọ̀ rẹ; lọ́dọ̀ ẹni tí ó sì kó ọ lẹ́rù, má sì ṣe padà bèèrè.

31. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti fẹ́ kí ènìyàn ṣe sí yín, kí ẹ̀yin sì ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn pẹ̀lú.

32. “Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ yín, ọpẹ́ kíni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ wọn.

33. Bí ẹ̀yin sì ṣoore fún àwọn tí ó ṣoore fún yín, ọpẹ́ kíni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́sẹ̀’ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.

34. Bí ẹ̀yin bá wín fún ẹni tí ẹ̀yin ń reti láti rí gbà padà, ọpẹ́ kínni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́sẹ̀’ pẹ̀lú ń yá ‘ẹlẹ́sẹ̀,’ kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà.

35. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀ta yín kí ẹ̀yin sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ ọ̀gá ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣeun fún aláìmoore àti fún ẹni búburú.

36. Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú.

37. “Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dáni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín.

38. Ẹ fifún ni, a ó sì fifún yín; òṣùnwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ̀n fún àyà yín: nítorí òṣùnwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ̀n, òun ni a ó padà fi wọ̀n fún yín.”

39. Ó sì pa òwe kan fún wọn: “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí?

40. Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí ó ba pé, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀.

41. “Èéṣe tí ìwọ sì ń wo èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí ìtì igi tí ń bẹ lójú ara rẹ?

Lúùkù 6