Lúùkù 3:4-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé ọ̀rọ̀ wòlíì Àìṣáyà pé,“Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù,‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,Ẹ mú ipa-ọ̀nà rẹ̀ tọ́.

5. Gbogbo ọ̀gbun ni a óò kún,Gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni a ó tẹ̀bẹ̀rẹ̀;Wíwọ́ ni a ó ṣe ní títọ́,àti ọ̀nà gbọ́ngun-gbọ̀ngun ni a o sọ di dídán.

6. Gbogbo ènìyàn ni yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.’ ”

7. Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀?

8. Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwá ní Ábúráhámù ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Ábúráhámù nínú òkúta wọ̀nyí.

9. Àti nísinsìnyí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà: gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a ké e lulẹ̀, a sì wọ́ ọ jù sínú iná.”

10. Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ha ṣe?”

11. Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”

12. Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”

13. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”

14. Àwọn ọmọ-ogun sì bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kíni àwa ó ṣe?”Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí ẹ má sì ṣe ka ẹ̀sùneké sí ẹnikẹ́ni; kí òwò ọ̀yà yín tó yín.”

15. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Jòhánù, bí òun ni Kírísítì bí òun kọ́;

Lúùkù 3