Lúùkù 19:23-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Èé ha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowó pamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, Èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’

24. “Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mínà náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó mínà mẹ́wàá.’

25. “Wọ́n sì wí fún un pé, ‘Olúwa, ó ní owó mínà mẹ́wàá.’

26. “Mo wí fún yín pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní, ni a ó fifún, àti lọ́dọ̀ ẹni tí kò ní èyí tí ó ní pàápàá a ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.

27. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá mi wọ̀nyí, tí kò fẹ́ kí èmi jọba lórí wọn ẹ mú wọn wá ìhínyìí, kí ẹ sì pa wọ́n níwájú mi!’ ”

28. Nígbà tí ó sì ti wí ǹkan wọ̀nyí tan, ó lọ ṣíwájú, ó ń gòkè lọ sí Jerúsálémù.

29. Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Bẹtifágè àti Bétanì ní òkè tí a ń pè ní Ólífì, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

30. Wí pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí: ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá.

31. Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”

32. Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn.

33. Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”

Lúùkù 19