4. Kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá;nítorí àwa tìkarawa pẹ̀lú a máa dáríji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbésè,Má sì fà wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ bìlísì.’ ”
5. Ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí yóò ní ọ̀rẹ́ kan, tí yóò sì tọ̀ ọ́ lọ láàrin ọ̀gànjọ́, tí yóò sì wí fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù àkàrà mẹ́ta.
6. Nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti àjò dé sọ́dọ̀ mi, èmi kò sì ní nǹkan tí èmi ó gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀.’
7. “Tí òun ó sì gbé inú ilé dáhùn wí fún un pé, ‘Má yọ mí lẹ́nu: a ti sé ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi si ń bẹ lórí ẹní pẹ̀lú mi: èmi kò lè dìde fi fún ọ!’
8. Mo wí fún yín, bí òun kò tilẹ̀ ti fẹ́ dìde kí ó fifún un nítorí tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí àwíìyánu rẹ̀, yóò dìde, yóò sì fún un pọ̀ tó bí ó ti ń fẹ́.
9. “Èmí sì wí fún yín, Ẹ bèèrè, a ó sì fifún un yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín.
10. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè, yóò rí gbà; ẹni tí ó sì ń wá kiri, yóò rí; àti ẹni tí ó kànkùn ni a ó ṣí i sílẹ̀ fún.
11. “Ta ni baba nínú yín tí ọmọ rẹ̀ yóò bèèrè (àkàrà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí yóò fún un ní òkúta? Tàbí bí ó bèèrè) ẹja, tí yóò fún un ní ejò dípò ẹja?
12. Tàbí bí ó sì bèèrè ẹ̀yin, tí yóò fún un ní àkéekée?
13. Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ó jẹ́ ènìyàn búburú bá mọ bí a ti í fi ẹ̀bùn dáradára fún àwọn ọmọ yín: mélóméló ha ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi Ẹ̀mí-Mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tí ó bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀!”
14. Ó sì ń lé ẹ̀mí ẹ̀sù kan jáde, tí ó sì yadi. Nígbà tí ẹ̀mí ẹ̀ṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀; ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn.
15. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn wí pé, “Nípa Béélísébúbù olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”
16. Àwọn ẹlòmíràn sì ń dán an wò, wọ́n ń fẹ́ àmì lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀run wá.
17. Ṣùgbọ́n òun mọ ìrò inú wọn, ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó ya ara rẹ̀ ní ipá, ni a ń sọ di àhoro; ilé tí ó sì ya ara rẹ̀ nípá yóò wó.
18. Bí Sàtánì sì yapa sí ara rẹ̀, ìjọba rẹ̀ yóò ha ṣe dúró? Nítorí ẹ̀yin wí pé, nípa Béélísébúbù ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.
19. Bí ó ba ṣe pé nípa Béélísébúbù ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù jáde, nípa tani àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde, nítorí náà àwọn ni yóò ṣe onídájọ́ yín.
20. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán.
21. “Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà.
22. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni tí ó ní agbára jù ú bá kọlù ú, tí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ a gba gbogbo ìhámọ́ra rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé lọ́wọ́ rẹ̀, a sì pín ìkógun rẹ̀.