17. Ẹ̀mí àti agbára Èlíjàh ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòótọ́; kí ó le pèṣè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa.”
18. Sakaráyà sì wí fún áńgẹ́lì náà pé, “Àmì wo ni èmi ó fi mọ èyí? Èmi sá ti di àgbà, àti Èlísábẹ́tì aya mi sì di arúgbó.”
19. Ańgẹ́lì náà sì dáhùn ó wí fún un pé, “Èmi ni Gébúrẹ́lì, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá.
20. Sì kíyèsí i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.”
21. Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sakaráyà, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì.
22. Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn sì kíyèsí wí pé ó ti rí ìran nínú tẹ́ḿpílì. ó sì ń se àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi.
23. Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé, ó lọ sí ilé rẹ̀.
24. Lẹ́yìn èyí ni Èlísábẹ́tì aya rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ ní oṣù márùn-ún, ó ní,
25. Ó sì wí pé “Báyìí ni Olúwa ṣe fún mi ní ọjọ́ tí ó ṣíjú wò mí, láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàrin àwọn ènìyàn.”
26. Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán áńgẹ́lì Gébúríẹ́lì sí ìlú kan ní Gálílì, tí à ń pè ní Násárẹ́tì,
27. sí wúndíá kan tí a ṣè lérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Jóṣéfù, ti ìdílé Dáfídì; orúkọ wúndíá náà a sì máa jẹ́ Màríà.
28. Ańgẹ́lì náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlààáfíà, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ńbẹ pẹ̀lú rẹ”
29. Ṣùgbọ́n ọkàn Màríà kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kínni èyí.
30. Ṣùgbọ́n àńgẹ́lì náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Màríà: nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
31. Ìwọ óò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní JÉSÙ.
32. Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é: Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún:
33. Yóò sì jọba lórí ilé Jákọ́bù títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.”
34. Nígbà náà ni Màríà bèèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tii mọ ọkùnrin.”
35. Ańgẹ́lì náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, àti agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò sìji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é.
36. Sì kíyèsí i, Èlísábẹ́tì ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọ kùnrin kan ní ògbólògbó rẹ̀: èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn.
37. Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”