Jòhánù 12:37-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́.

38. Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Ìsàíàh lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé:“Olúwa, tani ó gba ìwàásù wa gbọ́Àti ta ni a sì fi apá Olúwa hàn fún?”

39. Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Ìsáyà sì tún sọ pé:

40. “Ó ti fọ́ wọn lójú,Ó sì ti sé àyà wọn le;Kí wọn má baà fi ojú wọn rí,Kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,Kí wọn má baà yípadà, kí wọn má baà mú wọn láradá.”

41. Nǹkan wọ̀nyí ni Ìsáyà wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.

42. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisí wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sínágọ́gù:

43. Nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ.

44. Jésù sì kígbe ó sì wí pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, èmi kọ́ ni ó gbàgbọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi.

45. Ẹni tí ó bá sì rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi.

46. Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó wá sí ayé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ má ṣe wà nínú òkùnkùn.

Jòhánù 12