Jeremáyà 52:18-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Bákan náà, wọ́n tún kó àwọn ìkòkò, ọkọ́ àti ọ̀pá fìtílà, àwọn ọpọ́n, síbí àti gbogbo ohun èlò idẹ tí wọ́n ń lò níbi pẹpẹ lọ.

19. Balógun àwọn ìṣẹ́ náà kó àwokòtò, ohun ìfọná, ọpọ́n ìkòkò, ọ̀pá fìtílà, síbí àti ago wáìnì; èyí tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe lọ.

20. Àwọn ọ̀wọ̀n méjì agbada ńlá kan àti àwọn màlúù idẹ méjìlá tí ó wà lábẹ́ ìjókòó alágbèéká tí ó ṣe fún ibi pẹpẹ Olúwa, èyí tí ó kọjá èyí tí a lè gbéléwọ̀n.

21. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọ̀wọ̀n yìí ni o nà mí, ìwọn ìgbọ̀nwọ́ méjìdínlógún tí fífẹ̀ rẹ̀ sì tó ìgbọ̀nwọ́ méjìlá. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nípọn tó ìka mẹ́rin, wọ́n sì ní ihò nínú.

22. Ọ̀nà orí idẹ kan tó ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, wọ́n sì fi èṣo pomegiranátì ṣe ọ̀ṣọ́ sí i lára yíká. Ọ̀wọ́n kejì sì wà pẹ̀lú èṣo pomegiranátì tí ó jọra.

23. Pomegiranátì mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni ó wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àpapọ̀ gbogbo pomegiranátì sì jẹ́ ọgọ́rùn ún kan.

24. Balógun àwọn ẹ̀sọ́ mu Ṣeráyà olórí àwọn àlùfáà àti Ṣefanáyà tí ó jẹ́ igbá kejì rẹ̀ àti gbogbo àwọn asọ́nà.

25. Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú alásẹ tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn Ọba méje. Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà.

26. Nebusaradánì balógun náà kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn lọ sọ́dọ̀ Ọba Bábílónì ní Ríbílà.

Jeremáyà 52