10. Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn,títí yóò fi pa òrùngbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun yóò rúbọní ilẹ̀ Gúṣù ní odò Ẹ́fúrétà.
11. “Gòkè lọ sí Gílíádì, kí o sì mú ìkunra,ìwọ wúndíá Éjíbítì.Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn,kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.
12. Àwọn orílẹ̀ èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ,igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé.Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ,àwọn méjèèjì yóò sì dìjọ ṣubú papọ̀.”
13. Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremáyà wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadinésárì Ọba Bábílónì láti lọ dojú ìjà kọ Éjíbítì:
14. “Kéde èyí ní Éjíbítì, sì sọ ọ́ ní Nígídò,sọ ọ́ ní Mémífísì àti Táfánésì:‘Dúró sí àyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀,nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’
15. Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú?Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú.
16. Wọn yóò máa ṣubú léralérawọn yóò máa ṣubú lu ara wọn.Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padàsí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa,kúrò níbi idà àwọn aninilára.’
17. Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé,‘Ariwo lásán ni Fáráò Ọba Éjíbítì pa,ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’
18. “Bí èmi ti wà láàyè,” ni Ọba,ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ ogun wí pé,“nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tábórì láàrin àwọn òkè àtigẹ́gẹ́ bi Kámẹ́lì lẹ́bàá òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé.