Jeremáyà 2:30-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. “Nínú aṣán mo fìyà jẹ àwọnènìyàn yín, wọn kò sì gbaìbáwí, idà yín ti pa àwọnwòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bíkìnnìún tí ń bú ramúramù.

31. “Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ Olúwa:“Àbí ilẹ̀ ńlá olókùnkùnkí ló dé tí àwọn ènìyàn mi ṣesọ wí pé, ‘A ní àǹfààní látimáa rìn kiri? A kò sì ní wá sọ́dọ̀ rẹ mọ́?’

32. Wúndíá ha le gbàgbé ohunọ̀ṣọ́ rẹ̀ bí, tàbí ìyàwó ha le gbàgbé ohunọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀? Síbẹ̀, àwọnènìyàn mi ti gbàgbé mi ní ọjọ́ àìníye.

33. Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípaọ̀rọ̀ ìfẹ́! Àwọn obìnrin tí ó tilẹ̀burú yóò kẹ́kọ̀ọ́ láti àwọn ọ̀nà rẹ

34. Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá ẹ̀jẹ̀àwọn talákà aláìṣẹ̀bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ká wọnníbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé

35. Ṣíbẹ̀ nínú gbogbo èyíìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìsẹ̀kò sì bínú sími.’Èmi yóò ṣe ìdájọ́ mi lórí rẹnítorí pé ìwọ sọ pé, ‘Èmi kò tí ìdẹ́sẹ̀.’

36. Kí ló dé tí o fi ń lọ káàkiriláti yí ọ̀nà rẹ padà?Éjíbítì yóò dójú tì ọ́gẹ́gẹ́ bí i ti Ásíríà

Jeremáyà 2