1. Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Ádámù.Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run.
2. Ó dá wọn ní akọ àti abo, ó sì súre fún wọn. Nígbà tí ó dá wọn tan ó pè wọ́n ní “ènìyàn.”
3. Nígbà tí Ádámù di ẹni Àádóje ọdún (130), ó bí ọmọkùnrin kan tí ó jọ ọ́, tí ó jẹ́ àwòrán ara rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣétì.
4. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Ṣétì, ó tún wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin ọdún (800), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
5. Àpapọ̀ ọdún tí Ádámù gbé ní orí ilẹ̀ jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-ọgbọ̀n (930), ó sì kú.
6. Nígbà tí Ṣétì pé àrùnlélọ́gọ́rùn ún ọdún (105), ó bí Énọ́sì.
7. Lẹ́yìn ìgbà tí ó bí Énọ́sì, ó sì gbé fún ẹgbẹ̀rin-ó-lé-méje ọdún (807), ó sì bí àwọn; ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin.
8. Àpapọ̀ ọdún Ṣẹ́tì sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-méjìlá (912), ó sì kú.
9. Nígbà tí Énọ́sì di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún (90) ni ó bí Kénánì.
10. Lẹ́yìn tí ó bí Kénánì, ó wà láàyè fún ẹgbẹ̀rin-ọdún-ó-lé-mẹ́ẹ̀dógún (815), ó sì bí àwọn ọkùnrin àti obìnrin.
11. Àpapọ̀ ọdún Énọ́sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún-ọdún-ó-lé-márùn-ún (905), ó sì kú.
12. Nígbà tí Kénánì di àádọ́rin ọdún (70) ni ó bí Máhálálélì:
13. Lẹ́yìn tí ó bí Máhálálélì, ó wà láàyè fún òjìlélẹ́gbẹ̀rín ọdún (840), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbínrin.