7. Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa. Ó béèrè pé, ‘Ṣe bàbá yín sì wà láàyè?’ Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn?: A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni. Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín wá’?”
8. Júdà sì wí fún Ísírẹ́lì bàbá rẹ̀, “Jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ pẹ̀lú mi, a ó sì lọ ní kíákíá, kí àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa le yè, kí a má sì kú.
9. Èmi fúnra mi yóò ṣe onídùúró fún un, èmi ni kí o gbà pé o fi lé lọ́wọ́. Bí n kò bá sì mu un padà tọ̀ ọ́ wá, jẹ́ kí ẹ̀bi rẹ̀ kí ó jẹ́ tèmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi níwájú rẹ.
10. Bí ó bá ṣe pé a kò fi falẹ̀ ni, àwa ì bá ti lọ, à bá sì ti padà ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”
11. Nígbà náà ni Ísírẹ́lì baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe: Ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà-ìpara díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjíá, èso Písítakíò àti eso álímíndì
12. ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà. Bóyá ẹnìkan ló sèèsì fi ṣíbẹ̀.
13. Ẹ mú arákùnrin yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ki ẹ sì tọ arákùnrin náà lọ.
14. Kí Ọlọ́run alágbára jẹ́ kí ẹ rí àánú gbà lọ́dọ̀ ọkùnrin náà kí ó ba à le jẹ́ kí arákùnrin yín tí ó wà lọhun-un àti Bẹ́ńjámínì padà wá pẹ̀lú yín. Ní tèmi, bí mo bá pàdánù àwọn ọmọ mi, n ó sọ̀fọ̀ wọn náà ni.”
15. Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹ̀bùn náà àti owó ìlọ́po méjì àti Bẹ́ńjámínì, wọ́n sì yára lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Jóṣẹ́fù.
16. Nígbà tí Jóṣẹ́fù rí Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú wọn, ó sọ fún ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, “Mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ sí ilé mi, pa ẹran kí o sì se àsè; wọn ó jẹun ọ̀sán pẹ̀lú mi.”