15. Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹ̀bùn náà àti owó ìlọ́po méjì àti Bẹ́ńjámínì, wọ́n sì yára lọ sí ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Jóṣẹ́fù.
16. Nígbà tí Jóṣẹ́fù rí Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú wọn, ó sọ fún ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, “Mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ sí ilé mi, pa ẹran kí o sì se àsè; wọn ó jẹun ọ̀sán pẹ̀lú mi.”
17. Ọkùnrin náà sì ṣe bí Jósẹ́fù ti wí fún un, ó sì mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Jósẹ́fù.
18. Ẹ̀rù sì ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Jósẹ́fù. Wọ́n rò ó pé, “A mú wa wá sí ìhín nítorí owó tí a fi sí inú àpò wa ní ìgbà àkọ́kọ́. Ó fẹ́ bá wa jà, kí ó mú wa lẹ́rú kí ó sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.”
19. Nítorí náà wọ́n lọ bá ìránṣẹ́ Jósẹ́fù, wọ́n sì ba sọ̀rọ̀ ní ẹnu ọ̀nà à bá wọlé ilé náà.
20. Wọ́n wí pé, “Jọ̀wọ́ ọ̀gá” Ní ìgbà àkọ́kọ́ tí a wá ra oúnjẹ.
21. Ṣùgbọ́n níbi tí a ti dúró ní ọ̀nà láti sùn ní alẹ́, nígbà tí a tú àpò oúnjẹ wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá owó oúnjẹ tirẹ̀ tí ó rà lẹ́nu àpò láì lé, láì dín. Nítorí náà òun nìyí, a ti mu-un padà wá pẹ̀lú wa.
22. A sì tún mú owó mìíràn lọ́wọ́ láti fi ra oúnjẹ. A ò mọ ẹni tí ó fi owó wa sí ẹnu àpò.
23. Ó dáhùn pé, “Ó dára, ẹ má bẹ̀rù, Ọlọ́run yín, àní Ọlọ́run baba yín ni ó fi ìsúra sí inú àpò yín; mo rí owó tí ẹ san gbà.” Nígbà náà ni ó mú Símónì jáde tọ̀ wọ́n wá.
24. Ìránṣẹ́ náà mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Jósẹ́fù, ó fún wọn ní omi láti fi wẹ ẹsẹ̀ wọn nu, ó sì fún àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn lóúnjẹ pẹ̀lú.
25. Wọ́n pèṣè ẹ̀bùn wọn sílẹ̀ fún Jósẹ́fù di ọ̀sán nígbà tí yóò dé, nítorí wọ́n ti gbọ́ pé ibẹ̀ ni àwọn yóò ti jẹun ọ̀sán.
26. Nígbà tí Jósẹ́fù dé sí ilé, wọ́n kó àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n ti mú wá fún-un, wọ́n sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀.