Jẹ́nẹ́sísì 26:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ní ọdún náà, Ísáákì gbin ohun ọ̀gbìn sí ilẹ̀ náà ó sì kórè rẹ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rọ̀rún ni ọdún kan náà nítorí Ọlọ́run bùkún un.

13. Ó sì di ọlọ́rọ̀, ọrọ̀ rẹ̀ sì ń pọ̀ si, títí ó fi di ọlọ́rọ̀ gidigidi.

14. Ó ní ọ̀pọ̀lopọ̀ ẹran ọ̀sìn àti agbo ẹran àti àwọn ìránṣẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn Fílístínì ń ṣe ìlara rẹ̀.

15. Nítorí náà àwọn ará Fílístínì ru erùpẹ̀ di gbogbo kànga tí àwọn ìránṣẹ́ Ábúráhámù baba rẹ̀ ti gbẹ́.

16. Nígbà náà ni Ábímélékì wí fún Ísáákì pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ wa, nítorí tí ìwọ ti di alágbára púpọ̀ jù wá lọ.”

Jẹ́nẹ́sísì 26