Jẹ́nẹ́sísì 23:2-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. ó sì kú ní Kíríátì-Áríbà (ìyẹn ní Hébúrónì) ní ilẹ̀ Kénánì, Ábúráhámù lọ láti sọ̀fọ̀ àti láti sunkún nítorí Ṣárà.

3. Ábúráhámù sì dìde lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú aya rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ará Hítì wí pé,

4. “Iwo jẹ́ àjèjì àti àlejò láàrin yín, ẹ ta ilẹ̀ ìsìnkú fún mi kí èmi le sin òkú tí ó kú fún mi sí.”

5. Àwọn ará Hítì dá a lóhùn pé,

6. “Olúwa mi, gbọ́ tiwa, ó jẹ́ alágbára ọmọ-aládé láàrin wa, sin òkú rẹ sí ibojì tí ó dárajù nínú àwọn ibojì wa, kò sí ẹni tí yóò fi ibojì rẹ dùn ọ́ láti sin òkú rẹ sí.”

7. Nígbà náà ni Ábúráhámù dìde, ó sì tẹríba níwájú àwọn ará ilẹ̀ náà-àwọn ará Hítì.

8. Ó sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá ṣe pé, lóòótọ́ ni ẹ fẹ́ kí n sin òkú mi kúrò nílẹ̀, ẹ gbọ́ tèmi, ẹ bá mi bẹ Éfúrónì ọmọ Ṣóhárì,

9. kí ó ta ihò àpáta Mákípélà tí ó jẹ́ tirẹ̀ fún mi, èyí tí ó wà ni orí oko rẹ̀, kí ó tà á fún mi ni iye owó tí à ń ta irú rẹ̀ fún ilẹ̀ ìsìnkú láàrin yín.”

10. Éfúrónì ará Hítì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú, ó sì dá Ábúráhámù lóhùn lójú gbogbo àwọn ará ìlú tí ó wà níbẹ̀, lẹ́nu ibodè ìlú,

11. pé, “Rárá, Olúwa mi, Gbọ́ tèmi; mo fún ọ ní ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà níbẹ̀. Mo fún ọ níwájú gbogbo àwọn ènìyàn mi. Sin òkú rẹ ṣíbẹ̀.”

12. Ábúráhámù sì tún tẹríba níwájú àwọn ènìyàn ìlú náà,

13. Ó sì wí fún Éfúrónì lójú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ bá fẹ́, gbọ́ tèmi, èmi yóò san owó ilẹ̀ náà, gbà á lọ́wọ́ mi kí n lè sin òkú mi ṣíbẹ̀.”

14. Éfúrónì sì dá Ábúráhámù lóhùn pé,

Jẹ́nẹ́sísì 23