Jẹ́nẹ́sísì 17:11-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrin wa.

12. Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ̀yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrin Èmi àti irú ọmọ rẹ.

13. Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí fi owó rà, gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé.

14. Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a ko kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi”

15. Ọlọ́run wí fún Ábúráhámù pé, “Ní ti Ṣáráì, aya rẹ̀, ìwọ kì yóò pè é ní Ṣáráì bí kò ṣe Ṣárà.

16. Èmi yóò bùkún fún-un, Èmi yóò sì fun ọ ní ọmọkùnrin kan nípaṣẹ̀ rẹ̀. Èmi yóò bùkún-un, yóò sì di ìyá àwọn orílẹ̀ èdè, àwọn ọba àwọn orílẹ̀ èdè yóò sì ti ara rẹ̀ jáde wá.”

17. Ábúráhámù sì dojúbolẹ̀, ó rẹ́rìn-ín, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “A ó ha bí ọmọ fún ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún? Ṣárà tí í ṣe ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún yóò ha bímọ bí”.

18. Ábúráhámù sì wí fún Ọlọ́run pé, “Ṣá à jẹ́ kí Ísímáélì kí ó wà láàyè lábẹ́ ìbùkún rẹ.”

19. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo gbọ́, ṣùgbọ́n Ṣárà aya rẹ̀ yóò bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ísáákì, èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní májẹ̀mú ayérayé àti àwọn irú ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

20. Ṣùgbọ́n ní ti Ísímáélì, mo gbọ́ ohun tí ìwọ wí, èmi yóò bùkún fún-un ní tòótọ́, èmi ó sì mú un bí sí i, yóò sì pọ̀ sí i, òun yóò sì jẹ́ baba fún àwọn ọmọ-ọba méjìlá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá.

21. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú Ísáákì, ẹni tí Ṣárà yóò bí fún ọ ni ìwòyí àmọ́dún.”

22. Nígbà tí ó ti bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ tán, Ọlọ́run sì gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

23. Ní ọjọ́ náà gan-an ni Ábúráhámù mú Ísímáélì ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹrú tí a bí ní ilé rẹ̀ àti àwọn tí ó fi owó rà, ó sì kọ wọ́n ní ilà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kọ gbogbo ọkùnrin tí ń bẹ ní ilé rẹ̀ ní ilà gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa.

24. Ábúráhámù jẹ́ ẹni ọ̀kàndínlọ́gọ́rùnún (99) ọdún nígbà tí a kọ ọ́ ní ilà.

25. Ísímáélì ọmọ rẹ̀ jẹ́ ẹni ọdún mẹ́talá, (13).

26. Ábúráhámù pẹ̀lú rẹ̀ kọ ilà ní ọjọ́ náà gan-an.

27. Àti gbogbo ọkùnrin tí ó wà ní ilé Ábúráhámù, ìbá à ṣe èyí tí a bí ní ilé rẹ̀ tàbí èyí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àlejò ni a kọ ní ílà pẹ̀lú rẹ̀.

Jẹ́nẹ́sísì 17