1. Ní àsìkò yìí ni Ámúráfélì ọba Ṣínárì, Áríókù ọba Élásárì, Kédóláómérì ọba Élámù àti Tídálì ọba Góímù
2. jáde lọ láti bá Bérà ọba Ṣódómù, Bírísà ọba Gòmórà, Ṣínábù ọba Ádímà, Ṣémébérì ọba Ṣébóímù àti ọba Bélà (èyí-ni nì Ṣóárì) jagun.
3. Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí àfonífojì Ṣídímù (òkun iyọ̀).
4. Fún ọdún méjìlá gbáko ni wọ́n ti ń sin Kédóláómérì bí ẹrú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún kẹtàlá wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i.
5. Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kédóláómérì àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n sígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ara Ráfáímù ní Aṣilerótì-Kánáímù, àwọn ará Ṣúsítù ni Ámù, àwọn ará Émímù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriátaímù,
6. àti àwọn ará Hórì ní orí-òkè wọ̀nnì Ṣéírì, títí ó fi dé Eli-Páránì ní etí ijù.
7. Wọ́n sì tún yípadà lọ sí Ẹn-Mísífátì (èyí yìí ni Kádésì), wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Ámálékì, àti àwọn ará Ámórì tí ó tẹ̀dó sí Haṣaṣoní Támárì pẹ̀lú.
8. Nígbà náà ni ọba Ṣódómù, ọba Gòmórà, ọba Ádímà, ọba Ṣébóímù àti ọba Bélà (èyí ni Ṣóárì), kó àwọn ọmọ ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó-ogun wọn sí àfonífojì Ṣídímù,
9. láti kojú ìjà sí Kedolaómérì ọba Élámù, Tídà ọba Góímù, Ámúráfélì ọba Ṣínárì àti Áríókì ọba Élásà (ọba mẹ́rin kọjú ìjà sí ọba márùn-ún).
10. Àfonífojì Ṣídímù sì kún fún kòtò ọ̀dà-ilẹ̀, nígbà tí ọba Ṣódómù àti ọba Gòmórà sì ṣá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà subú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè.
11. Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Ṣódómù àti Gòmórà àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ.
12. Wọ́n sì mú Lọ́tì ọmọ arákùnrin Ábúrámù tí ń gbé ní Ṣódómù àti gbogbo ohun-ìní rẹ̀.
13. Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Ábúrámù, ará Ébérù. Ábúrámù sá ti tẹ̀dó sí igbó igi Óákù tí ó jẹ́ ti Mámúrè ará Ámórì, arákùnrin Ésíkólì àti Ánérì: àwọn ẹni tí ó ń bá Ábúrámù ní àṣepọ̀.
14. Nígbà tí Ábúrámù gbọ́ wí pé, a di Lọ́tì ní ìgbékùn, o kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ́ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó-lé-lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì ènìyàn (318), ó sì lépa wọn títí dé Dánì.