8. Àwọn ará ìlú Sídónì àti Árífádì ni àwọn ìtukọ̀ rẹ̀àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tírè,tí wọ́n wà nínú rẹ ni àwọn àtukọ̀ rẹ.
9. Àwọn àgbà Gíbálì,àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀,wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ,gbogbo ọkọ̀ ojú òkunàti àwọn atukọ̀-òkunwá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
10. “ ‘Àwọn ènìyàn Páṣíà, Lídíà àti Pútìwà nínú jagunjagun rẹàwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ.Wọ́n gbé àpáta àti àsíborí wọn rósára ògiri rẹ,wọn fi ẹwà rẹ hàn.
11. Àwọn ènìyàn Árífádì àti Hélékìwà lórí odi rẹ yíká;àti àwọn akọni Gámádì,wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ.Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ;wọn ti mú ẹwà rẹ pé.
12. “ ‘Táṣíṣì ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin tanúnganran àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.
13. “ ‘Àwọn ará Gíríkì, Túbálì, Jáfánì àti Méṣékì, ṣòwò pẹ̀lú rẹ: wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàsípààrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.
14. “ ‘Àwọn ti ilé Béti Tógárímà ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin-ogun àti ìbàákà ṣòwò ní ọjà rẹ.
15. “ ‘Àwọn ènìyàn Ródísì ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ onibárà rẹ̀; wọ́n mú eyín-erin àti igi ébónì san owó rẹ.
16. “ ‘Árámù ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ òkúta iyebíye, òwú elésèé àlùkò, iṣẹ́ ọ̀nà tí a fi abẹ́rẹ́ ṣe, asọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.
17. “ ‘Júdà àti Ísírẹ́lì, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Mínnítì, àkàrà àdídùn; pannági, oyin, epo àti ìpara olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.
18. “ ‘Dámásíkù, ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helíbónì, àti irun àgùntàn funfun.
19. “ ‘Àwọn ará Dánì àti Gíríkì láti Úsálì ra ọjà títà rẹ; irin dídán, káṣíà ati kálámù ni àwọn ohun pàsípààrọ̀ ní ọjà rẹ.
20. “ ‘Dédánì ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.