14. “Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni àǹfààní láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu-bodè wọ inú ìlú náà.
15. Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbérè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké.
16. “Èmi, Jésù, ni ó rán ańgẹ́lì mi láti jẹ̀rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòngbò àti irú-ọmọ Dáfídì, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.”
17. Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.
18. Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkú ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fí kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un.