Ìfihàn 13:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo sì rí ẹranko kan ń ti inú òkun jáde wá, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá, lórí àwọn ìwo náà ni orúkọ ọ̀rọ̀-òdì wà.

2. Ẹranko tí mo rí náà sì dàbí ẹkùn, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí tí béárì ẹnu rẹ̀ sì dàbí tí kìnnìún: dírágónì náà sì fún un ni agbára rẹ̀, àti ìtẹ́ rẹ̀, àti àṣẹ ńlá.

3. Mo sì rí ọ̀kan nínú àwọn orí rẹ̀ bí ẹni pé a ṣá a pa, a sì tí wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ náà sàn, gbogbo ayé sì fi ìyanu tẹ̀lé ẹranko náà.

4. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún dírágónì náà, nítorí tí o fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, wí pé, “Ta ni o dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó sì lè bá a jagun?”

5. A sì fún un ni ẹnu láti má sọ ohun ńlá àti ọ̀rọ̀ òdì, a sì fi agbára fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni oṣù méjìlélógójì.

6. Ó sì ya ẹnu rẹ̀ ni ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rẹ̀, àti sí àgọ́ rẹ̀, àti sí àwọn tí ń gbé ọ̀run.

7. A sì fún-un láti máa bá àwọn ènìyàn-mímọ́ jagun, àti láti ṣẹ́gun wọn: a sì fi agbára fún un lórí gbogbo ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti èdè, àti orílẹ̀.

8. Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlúkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé-ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

Ìfihàn 13