Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4:33-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Agbára ńlá ni àwọn àpósítélì sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jésù Olúwa, Oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn.

34. Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá.

35. Wọ́n sì fi í lélẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ àwọn àpósítélì, wọn sì ń pín fún olukúlúkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe aláìní sí.

36. Àti Jóṣéfù, tí a ti ọwọ́ àwọn àpósítélì sọ àpèlé rẹ̀ ní Bánábà (ìtúmọ̀ èyí tí ń jẹ Ọmọ-Ìtùnú), ẹ̀yà Léfì, àti ará Sáípúrọ́sì.

37. Ó ní ilẹ̀ kan, ó tà á, ó mú owó rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn àpósítélì.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4