Ìṣe Àwọn Àpósítélì 3:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kan Pétérù àti Jòhánù jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán.

2. Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ lẹ́nu-ọ̀nà tẹ́ḿpìlì ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ,

3. Nígbà tí ó rí Pétérù àti Jòhánù bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹ́ḿpìlì, ó sagbe.

4. Pétérù sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Jòhánù, ó ní “Wò wá!”

5. Ó sì fiyèsí wọn, ó ń réti láti rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn.

6. Pétérù wí pé, “Góòlù àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fifún ọ: Ní orúkọ Jésù Kírísítì ti Násárẹ́tì, dìde kí o sì máa rìn.”

7. Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkán náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun.

8. Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹ́ḿpìlì lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run.

9. Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run:

10. Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe lẹ́nu ọ̀nà Dáradára ti tẹ́ḿpìlì náà; hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀.

11. Bí arọ ti a mú láradá sì ti di Pétérù àti Jòhánù mú, gbogbo ènìyàn júmọ́ sure tọ̀ wọ́n lọ ni ìloro ti a ń pè ní ti Sólómónì, pẹ̀lú ìyàlẹ́nú ńlá.

12. Nígbà tí Pétérù sì rí i, ó dáhùn, ó wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, è é ṣe tí háà fi ń ṣe yín sí èyí? Tàbí è é ṣe ti ẹ̀yin fi tẹjúmọ́ wa, bí ẹni pé agbára tàbí ìwà mímọ́ wa ni àwa fi ṣe é ti ọkùnrin yìí fi ń rìn?

13. Ọlọ́run Ábúráhámù, àti ti Ísáàkì, àti ti Jákọ́bù, Ọlọ́run àwọn baba wa, òun ni ó ti yin Jésù ìránṣẹ́ rẹ̀ lógo; ẹni tí ẹ̀yin ti fi lé wọn lọ́wọ́, tí ẹ̀yin sì sẹ́ níwájú Pílátù, nígbà tí ó ti pinnu rẹ̀ láti dá a sílẹ̀.

14. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin sẹ́ Ẹni-Mímọ́ àti Olóòtọ̀ náà, ẹ̀yin sì béèrè kí a fi apànìyàn fún un yín.

15. Ẹ̀yin sì pa ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìyè, ẹni tí Ọlọ́run sì ti jí dìde kúrò nínú òkú; ẹlẹ́rìí èyí ti àwa jẹ́.

16. Nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Jésù, òun ni ó mú ọkùnrin yìí láradá, ẹni tí ẹ̀yin rí, tí ẹ sì mọ̀. Orúkọ Jésù àti ìgbàgbọ́ tí ó wá nípa rẹ̀ ni ó fún un ní ìlera pípé ṣáṣá yìí ni ojú gbogbo yín.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 3