29. Nítorí wọ́n tí rí Tírófímù ará Éfésù pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Pọ́ọ̀lù mú wá sínú tẹ́ḿpílì.
30. Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdo, àwọn ènìyàn sì súré jọ: wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹ́ḿpílì: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn.
31. Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerúsálémù dàrú.
32. Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Pọ́ọ̀lù.
33. Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì bèèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe.
34. Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun.
35. Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà-ipá àwọn ènìyàn.