Ìṣe Àwọn Àpósítélì 21:15-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Lẹ́yìn ijọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerúsálémù.

16. Nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti Kéṣáríà bá wa lọ, wọ́n sì mú wa lọ sí ilé Múnásónì ọmọ-ẹ̀yìn àtijọ́ kan ara Sàìpúrọ́sì, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa óò dé sí.

17. Nígbà tí a sì dé Jerúsálémù, àwọn arákùnrin sì fi ayọ̀ gbà wá,

18. Ní ijọ́ kejì, a bá Pọ́ọ̀lù lọ sọ́dọ̀ Jákọ́bù; gbogbo àwọn alàgbà sì wà níbẹ̀.

19. Nígbà tí ó sì kí wọn tan, ó ròyìn lẹsẹẹsẹ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe láàrin àwọn aláìkọlà nípa iṣẹ́-ìránṣẹ́ rẹ̀.

20. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 21