13. Lẹ̀yìn tí wọn sì dákẹ́, Jákọ́bù dáhùn, wí pé, “Ará, ẹ gbọ́ tèmi:
14. Símóòní ti róyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojúwo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀.
15. Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bá ṣe dédé; bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:
16. “ ‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni èmi ó padà,èmi ó sì tún àgọ́ Dáfídì pa tí ó ti wó lulẹ̀:èmi ó sì tún ahoro rẹ̀ kọ́,èmi ó sì gbé e ró:
17. kí àwọn ènìyàn ìyókù lè máa wá Olúwa,àti gbogbo àwọn aláìkọlà tí a ń fi orúkọ mi pè.’ni Olúwa wí, ta ni ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí
18. Ní Olúwa wí, ẹni tí ó sọ gbogbonǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá,
19. “Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu.
20. Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fà sẹ̀hín kúrò nínú èérí òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀.
21. Mósè nígbà àtijọ́, sá ní àwọn ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú sínágọ́gù ni ọjọ́jọ́ ìsinmi.”