5. Òun ni ọba lórí Jéṣúrúnìní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọ pọ̀,pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì
6. “Jẹ́ kí Rúbẹ́nì yè kí ó má ṣe kú,tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.”
7. Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Júdà:“Olúwa gbọ́ ohùn Júdàkí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá.Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un,kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta rẹ̀!”
8. Ní ti Léfì ó wí pé:“Jẹ́ kí Túmímù àti Úrímù rẹ kí ó wàpẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ.Ẹni tí ó dánwò ní Másà,ìwọ bá jà ní omi Méríbà.
9. Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé,‘Èmi kò buyì fún wọn.’Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀,tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀,ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀,ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.
10. Ó kọ́ Jákọ́bù ní ìdájọ́ rẹ̀àti Ísírẹ́lì ní òfin rẹ̀.Ó mú tùràrí wá ṣíwájú rẹ̀àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.
11. Bù sí ohun ìní rẹ̀, Olúwa,kí o sì tẹ́wọ́gba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i;kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”
12. Ní ti Bẹ́ńjámínì ó wí pé:“Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrin èjìká rẹ̀.”
13. Ní ti Jóṣẹ́fù ó wí pé:“Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ,fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrìàti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀;
14. àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wáàti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;
15. pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanìàti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;
16. Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Jósẹ́fù,lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀.
17. Ní ọlá ńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀ èdè,pàápàá títí dé òpin ayé.Àwọn ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún Éfúráímù,àwọn sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè.”