Deutarónómì 33:20-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ní ti Gádì ó wí pé:“Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gádì gbilẹ̀!Gádì ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,ó sì fa apá ya, àní àtàrí.

21. Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;ìpín olórí ni a sì fi fún un.Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,ó mú òdodo Olúwa se,àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”

22. Ní ti Dánì ó wí pé:“Ọmọ kìnnìún ni Dánì,tí ń fò láti Básánì wá.”

23. Ní ti Náfítánì ó wí pé,“Ìwọ Náfítánì, Náfítánì kún fún ojú rere Ọlọ́runàti ìbùkún Olúwa;yóò jogún ìhà ìwọ̀ oòrùn àti gúṣù.”

24. Ní ti Áṣérì ó wí pé:“Ìbùkún ọmọ ni ti Áṣérì;jẹ́ kí ó rí ojú rere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀kí ó sì ri ẹṣẹ̀ rẹ̀ sínú òróró.

25. Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ,agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀.

Deutarónómì 33