3. Kí o kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí o bá ti ń ré kọjá láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ.
4. Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ébálì, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun.
5. Kọ́ Pẹpẹ ṣíbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn.
6. Kí o kọ́ pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú òkúta nínú pápá kí o sì sun ẹbọ ni orí i rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ.
7. Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.
8. Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”
9. Nígbà náà ni Móṣè àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, sọ fún Ísírẹ́lì pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Ísírẹ́lì, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí.
10. Gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”
11. Ní ọjọ́ kan náà Móṣè pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.
12. Nígbà tí o bá ti kọjá a Jọ́dánì, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gérísímù láti ṣúre fún àwọn ènìyàn: Símónì, Léfì, Júdà, Ísákárì, Jóṣẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì.
13. Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ébálì láti gé ègún: Rúbẹ́nì, Gádì, àti Ásérì, àti Ṣébúlúnì, Dánì, àti Náfitanì.
14. Àwọn ẹ̀yà Léfì yóò ké sí gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì ní ohùn òkè:
15. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ onísọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
16. “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójú ti baba tàbí ìyá rẹ̀”Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”