2 Kíróníkà 33:9-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ṣùgbọn Mánásè mú kí Júdà àti àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí Olúwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

10. Ọlọ́run bá Mánásè sọ̀rọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọbi ara sí i

11. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mú àwọn alákòóso ọmọ ogun ọba Ásíríà láti dojúkọ wọ́n, tí ó mú Mánásè lẹ́lẹ́wọ̀n, ó fi ìkọ́ mú-un ní imú rẹ̀, ó dè é pẹ̀lú Ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ ó sì mú-un lọ sí Bábílónì.

12. Nínú ìpọ́njú rẹ̀, ó wá ojú rere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀.

13. Nígbà tí ó sì gbàdúrà síi, inú Olúwa dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jérúsálẹ́mù àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Mánásè mọ̀ wí pé Olúwa ni Ọlọ́run.

14. Lẹ́yìn èyí, ó tún ìta ògiri ìlú ńlá Dáfídì kọ́. Ìhà ìwọ̀ oòrùn orísun Gíhónì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ní jìnnà réré bí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ẹja àti yíyí orí òkè Ófélì; ó se é ní gíga díẹ̀. Ó mú àwọn alákòóso ológun wà ní ìdúró nínú gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi ní Júdà.

15. Ó pa gbogbo àwọn Ọlọ́run àjòjì run. Ó sì hú gbogbo àwọn ère kúrò nínú ilé Olúwa, pẹ̀lú gbogbo àwọn pẹpẹ tí ó ti kọ́ ní òkè ilé Olúwa àti ní Jérúsálẹ́mù; ó sì kó wọn jáde kúrò nínú ìlú.

16. Nígbà náà ó mú àwọn pẹpẹ padà bọ̀ sípò. Ó sì rú ọrẹ ìdàpọ̀ àti ọrẹ ọpẹ́ lórí rẹ̀. Ó sì sọ fún Júdà láti sin Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.

17. Àwọn ènìyàn, bí ó ti wù kí ó rí, tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ ní àwọn ibi gíga. Ṣùgbọ́n sí Olúwa Ọlọ́run wọn nìkan.

18. Àwọn isẹ́ yòókù ti ìjọba Mánásè pẹ̀lú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọ́run rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn aríran sọ sí i wà nínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì.

19. Àdúrà rẹ̀ àti bí inú Ọlọ́run ṣe dùn sí àdúrà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti àìsòótọ́ àti àwọn ipò níbi tí ó kọ́ àwọn ibi gíga sí, ó sì gbé àwọn òpó Áṣérà àti àwọn òrìṣà kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sínu ìwé ìrántí àwọn aríran.

20. Mánásè sinmi pẹ̀lú àwọn bàbá rẹ̀, a sì sin ín sínú ààfin rẹ̀. Ámónì ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba

21. Ámónì jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjì.

22. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ Mánásè ti ṣe. Ámónì sìn ó sì rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà tí Mánásè ti ṣe.

23. Ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i baba a rẹ̀ Mánásè. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Olúwa: Ẹ̀bi Ámónì ń ga sí i.

2 Kíróníkà 33