2 Kíróníkà 19:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí Jéhóṣáfátì ọba Júdà padà ní àlàáfíà sí ilé rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù,

2. Jéhù aríran, ọmọ Hánánì jáde lọ láti lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Sé ìwọ yóò máa ran ènìyàn búburú lọ́wọ́, kí o sì fẹ́ràn àwọn tí ó kórìíra Olúwa? Nítorí èyí, ìbínú Olúwa wà lórí wa.

3. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun rere wà nínú rẹ, nítorí tí ìwọ ti mú àwọn ilé àwọn ère òrìṣà kúrò, tí o sì múra ọkàn rẹ láti wá Ọlọ́run.”

4. Jéhóṣáfátì sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù ó sì jáde lọ padà láàárin àwọn ènìyàn láti Béríṣébà dé òkè ìlú Éfúráímù, ó sì mú wọn padà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run baba wọn.

5. Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi, Júdà.

6. Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsí ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́.

7. Nísinsin yìí jẹ́kí ìbẹ̀rù Olúwa kí ó wá sí orí rẹ̀. Ṣe ìdájọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nítorí pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run kò sí àìṣedéédéé tàbí ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”

8. Ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú, Jéhóṣáfatì yan díẹ̀ lára àwọn Léfì, àwọn àlùfáà àti àwọn olórí ìdílé Ísírẹ́lì si pípa òfin Olúwa mọ́ àti láti ṣe ìdájọ́. Wọn sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.

2 Kíróníkà 19