Ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú, Jéhóṣáfatì yan díẹ̀ lára àwọn Léfì, àwọn àlùfáà àti àwọn olórí ìdílé Ísírẹ́lì si pípa òfin Olúwa mọ́ àti láti ṣe ìdájọ́. Wọn sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù.