1 Tímótíù 1:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Sí Tímótíù ọmọ mi nínú ìgbàgbọ́:Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jésù Kírísítì Olúwa wa.

3. Bí mo se rọ̀yín nígbàtí mò ń lọ sí Makedóníà, ẹ dúró ní Éfésù, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́

4. kí wọ́n má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn-asán, àti ìtàn-ìran aláìlópin. Irú èyí máa ń mú iyàn jíjà wá dípò iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run èyí tí í ṣe ti ìgbàgbọ́.

5. Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn.

6. Àwọn ẹlòmíràn ti yapa kúrò tí wọ́n sì yà sápákan sí ọ̀rọ̀ asán.

7. Wọ́n ń fẹ́ ṣe olùkọ́ òfin; òye ohun tí wọ́n ń wí kò yé wọn tàbí ti ohun tí wọ́n ń fi ìgboyà tẹnumọ́.

8. Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára.

9. Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá àti àwọn apànìyàn,

10. fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro.

11. Gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi.

1 Tímótíù 1