1 Sámúẹ́lì 2:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì ń ṣe ìráńṣẹ́ níwájú Olúwa, ọmọdé, ti a wọ̀ ní éfódì ọ̀gbọ̀.

19. Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ ìlekè péńpé fún un, a sì máa mu wá fún un lọdọọdún, nígbà tí ó bá bá ọkọ rẹ̀ gòkè wá láti ṣe ìrúbọ ọdún.

20. Élì súre fún Elikánà àti aya rẹ̀ pé, “Kí Olúwa fún ọ ní irú-ọmọ láti ara obìnrin yìí wá, nítorí ẹ̀bùn tí ó béèrè tí ó sì tún fún Olúwa.” Wọ́n sì lọ sí ilé wọn.

21. Olúwa si bojú wo Hánà, ó sì lóyún, ó bí ọmọkùnrin mẹ́ta àti ọmọbìnrin méjì. Sámúẹ́lì ọmọ náà sì ń dàgbà níwájú Olúwa.

22. Élì sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì; àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.

23. Ó sì wí fún wọn pé, kí ni ó ti ri “Èétirí tí èmi fi ń gbọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí yín? Nítorí tí èmi ń gbọ́ iṣẹ́ búburú yín láti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.

24. Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí kì ṣe ìròyìn rere èmi gbọ́; ẹyin mú ènìyàn Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀.

25. Bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì, onídàájọ́ yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí Olúwa, tani yóò bẹ̀bẹ̀ fún un?” Wọn kò sì fi etí sí ohùn baba wọn, nítorí tí Olúwa ń fẹ́ pa wọ́n.

26. Ọmọ náà Sámúẹ́lì ń dàgbà, ó sì rí ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa, àti ènìyàn pẹ̀lú.

27. Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ Élì wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí, ‘Èmi fi ara mi hàn ní gbangba fún ilé baba rẹ̀, nígbà tí wọ́n ń bẹ nínú ilé Fáráò.

1 Sámúẹ́lì 2