1. Olúwa, Ọlọ́run tí o gba mí là,ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ.
2. Jẹ́ kí àdúrà mi kí o wá sí iwájú Rẹ;dẹ etí Rẹ̀ sí igbe mi.
3. Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njúọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.
4. A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀èmi dà bí ọkùnrin tí kò ni agbára.
5. A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkúbí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.
6. Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jínjìn,ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
7. Ìbínú Rẹ ṣubú lé mi gidigidi;ìwọ ti fi àwọn ìjì Rẹ̀ borí mi.
8. Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mí kúrò lọ́wọ́ miìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.A há mi mọ́, èmi kò sì lé è jáde;
9. Ojú mi káànú nítorí ìpọ́njú.Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;mo na ọwọ́ mí jáde sí ọ.