Sáàmù 74:18-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn Rẹ, Olúwabí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ Rẹ jẹ́.

19. Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà Rẹ fún ẹranko ìgbẹ́ búburú;Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn Rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.

20. Bojúwo májẹ̀mu Rẹ,nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.

21. Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjújẹ́ kí àwọn aláìní àti talákà yin orúkọ Rẹ.

22. Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara Rẹ̀ rò;rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn Rẹ ní gbogbo ọjọ́.

23. Má ṣe gbàgbé ohun àwọn ọ̀tá Rẹ,bíbú àwọn ọ̀tá Rẹ, tí ó ń pọ̀ síi nígbà gbogbo.

Sáàmù 74