Sáàmù 73:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọnwọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

11. Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀?Ọ̀gá ògo ha ní ìmọ̀ bí?”

12. Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyíènìyàn asán, wọn ń pọ̀ ní ọrọ̀.

13. Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́;nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́sẹ̀.

14. Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu;a sì ń jẹ mí níyà ní gbogbo òwúrọ̀.

15. Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,”Èmi ó ṣẹ̀sí ìran àwọn ọmọ Rẹ̀.

16. Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí,O jẹ́ ìnilára fún mi.

17. Tí tí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run;Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi,

18. Lótítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.

19. Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìíbí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọn pátapáta!

20. Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa,ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.

Sáàmù 73