Sáàmù 73:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítòótọ̀ Ọlọ́run dára fún Ísírẹ́lì,fún àwọn ọlọ́kàn funfun.

2. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán;ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.

3. Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣeféfénígbà tí mo bá rí ọlá àwọn ènìyàn búburú.

4. Wọn kò ṣe wàhálà;ara wọn mókun wọn sì lágbára.

5. Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ si ènìyàn;a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlomíràn.

6. Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn;ìwà ìpá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.

7. Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìsòdodo ti wá;ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdiwọ̀n

8. Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀ òdì nítiìnilára, wọn ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.

9. Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀runahọ́n wọn gba ipò ayé.

10. Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọnwọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

11. Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀?Ọ̀gá ògo ha ní ìmọ̀ bí?”

Sáàmù 73