Sáàmù 59:6-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Wọ́n padà ní àṣálẹ́,wọ́n ń gbó bí àwọn ajá,wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri.

7. Kíyèsí ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu:wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn,wọn sì wí pé, “Ta ní ó le gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”

8. Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, yóò fi wọ́n rẹ́rin-ínÌwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè.

9. Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ;nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,

10. Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi.Yóò sì jẹ́ kí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gún lórí àwọn ọ̀tá ìfẹ́ àwọn ọ̀ta mi.

11. Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa,kí àwọn ènìyàn mí má ba à gbàgbé.Nínú agbára Rẹ̀, jẹ́ kí wọ́n máa rìn kiri,kí ó sì Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

12. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn,ni ọ̀rọ̀ ètè wọn,kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn.Nítorí ẹ̀gàn àti èké tí wọn ń sọ,

13. Pa wọn run nínú ìbínú,run wọ́n di ìgbà tí wọ́n kò ní sí mọ́.Nígbà náà ní yóò di mímọ̀ dé òpin ayépé Ọlọ́run jọba lórí Jákọ́bù. Sela

14. Wọ́n padà ní àsálẹ́,wọn ń gbó bí àwọn ajáwọ́n ń rìn ìlú náà káàkiri.

Sáàmù 59