Sáàmù 56:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbọ́nára lépa mi;ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjàsí mi, wọn ń ni mi lára.

2. Àwọn ọ̀ta mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.

3. Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bàmí,èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.

4. Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ Rẹnínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà míkí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?

Sáàmù 56