3. Ọlọ́run ń bọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kì yóò dákẹ́,iná yóò máa jó níwájú Rẹ̀,àti ní àyíká Rẹ̀ ni ẹ̀fúfù líle yóò ti máa jà ká.
4. Yóò sì pe àwọn ọ̀run láti òkè wá jọ àti ayé,kí o le máa ṣe ìdárò àwọn ènìyàn Rẹ̀.
5. “Kó àwọn ènìyàn mímọ́ jọ fún miàwọn tí wọn fi ẹbọ dá májẹ̀mú fún mi”.
6. Àwọn ọ̀run sọ̀rọ̀ òdodo Rẹ̀,Nítorí òun fúnrarẹ̀ ni onídàájọ́
7. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi yóò si sọ̀rọ̀, ìwọ Ísírẹ́lì, èmi yóò jẹrìí sí ọ:èmi ní Ọlọ́run, àní Ọlọ́run Rẹ.
8. Èmi kí yóò bá ọ wínítorí àwọn ìrúbọ Rẹ̀tàbí ọrẹ̀ ẹbọ sísun Rẹ, èyí tí ó wà níwájú miní ìgbà gbogbo.
9. Èmí kò fẹ́ kí ó mú akọ màlúù láti inú ilé tí ó kọ fún untàbí kí o mú ewúré látiinú agbo ẹran Rẹ̀
10. Nítorí gbogbo ẹran igbó ni tèmíàti ẹran ọ̀sìn lórí ẹgbẹ̀rún òkè.
11. Èmi mọ gbogbo ẹyẹ ní orí àwọn òkè ńláàti gbogbo ẹ̀dá alààyé tí ó wà ní orí ilẹ ni tèmi
12. Bí ebi tílẹ̀ ń pá mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbotí ó wa ní inú Rẹ̀.