Sáàmù 34:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ Rẹ̀ lékè.

4. Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.

5. Wọ́n wòó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;ojú kò sì tì wọ́n

6. Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn Rẹ̀;ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú Rẹ̀.

7. Ángẹ́lì Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀ káó sì gbà wọ́n.

8. Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú Rẹ̀.

Sáàmù 34