Sáàmù 33:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ẹyin Olúwa pẹ̀lú dùùrù;ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.

3. Ẹ kọ orin tuntun sí i;ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin síi,pẹ̀lú ariwo ńlá.

4. Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin,gbogbo iṣẹ́ Rẹ̀ ni à ń ṣenínú òtítọ́.

5. Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.

6. Nípaṣẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu Rẹ̀.

7. Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;ó sì fi ibú sí ilé ìṣúra gbogbo.

8. Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa:jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayékí ó wà nínú ìbẹ̀rù Rẹ̀.

9. Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹó sì dúró ṣinṣin.

10. Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀ èdè wá sí asán;ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákìí.

11. Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,àní ìrò inú Rẹ̀ láti ìrandíran ni.

Sáàmù 33