Sáàmù 31:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ OlúwaMo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”

15. Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ Rẹ;gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá miàti àwọn onínúnibíni.

16. Jẹ́ kí ojú ù Rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìrànṣẹ́ Rẹ lára;Gbà mí nínú ìfẹ́ẹ̀ Rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

17. Má ṣe jẹ́ kí á fi mí sínú ìtijú, Olúwa;nítorí pé mo ké pè ọ́;jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú;jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.

18. Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn.wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.

19. Báwo ni títóbi oore Rẹ̀ ti pọ̀ tó,èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ,èyí tí ìwọ rọ̀jò Rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàntí wọ́n fi ọ́ se ibi ìsádi wọn.

20. Ní abẹ́ ibòji iwájú Rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ síkúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;ní ibùgbé Rẹ o mú wọn kúrò nínú ewukúrò nínú ìjà ahọ́n.

Sáàmù 31