Sáàmù 30:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi yóò kókìkíì Rẹ, Olúwa,nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékètí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀ta mi kí ó yọ̀ mí.

2. Olúwa Ọlọ́run mi, èmí ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́ìwọ sì ti wò mí sàn.

3. Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkúmú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má baà lọ sínú ihò.

4. Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ Rẹ̀ mímọ́.

Sáàmù 30