3. Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ Rẹ̀jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
4. Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn Rẹ̀ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé
5. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá Rẹ̀kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.
6. Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọnàti idà olójú méjì ní ọ́wọ́ wọn.
7. Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀ èdè,àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
8. Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọnàti láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
9. Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ Rẹ̀ sí wọnèyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.