1. Ìyìn sí Olúwa àpáta mi,ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,àti ìka mi fún ìjà.
2. Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,ẹni tí ó tẹ́rí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi
3. Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún-ún,tàbi ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa Rẹ̀?
4. Ènìyàn rí bí èmi;ọjọ́ Rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.