Sáàmù 102:15-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Àwọn ayé yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo Rẹ.

16. Torí tí Olúwa yóò gbé Síónì ró, yóò farahàn nínú ògo Rẹ̀.

17. Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;kì yóò si gan ẹ̀bẹ̀ wọn.

18. Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:

19. “Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ Rẹ̀ wáláti ọ̀run wá ni ó bojúwo ayé,

20. Láti gbọ́ ìrora ará túbú, lati túàwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”

21. Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ni Síónìàti ìyìn Rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù.

22. Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àtiìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.

23. Ní ipa ọ̀nà mi, ó Rẹ agbára mi sílẹ̀,ó gé ọjọ́ mi kúrú.

24. Èmi sì wí pé;“Ọlọ́run mi, Má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún Rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.

25. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpilẹ̀ ayé sọlẹ̀,ọrun si jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Rẹ.

Sáàmù 102