Òwe 9:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”

13. Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo;ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláì ní ìmọ̀.

14. Ó jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀lórí ìjòkó níbi tí ó ga jù láàrin ìlú,

15. ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ,tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.

16. “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!”Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.

17. “Omi tí a jí mu dùnoúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”

18. Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀,pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.

Òwe 9